17. Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ìwọ tí o ń gbé ní abẹ́ ààbò.
18. Nítorí èyí ni Olúwa wí:“Ní àkókò yìí,èmi yóò gbọn àwọn tí ó ń gbéilẹ̀ náà jáde. Èmi yóò mú ìpọ́njúbá wọn, kí wọn kí ó lè rí wọn mú.”
19. Ègbé ni fún mi nítorí ìpalára mi!Ọgbẹ́ mi jẹ́ èyí tí kò lè sàn, bẹ́ẹ̀ nimọ sọ fún ara mi,“Èyí ni àìsàn mi, mo sì gbọdọ̀ fi orí tì í.”
20. Àgọ́ mi bàjẹ́, gbogbo okùn rẹ̀ sì já.Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́Kò sí ẹnìkankan pẹ̀lú mi mọ́, báyìí kò sí ẹni tí yóòná àgọ́ mi tàbí ṣe ibùgbé fún mi