11. “Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kékèèké tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ”
12. Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀,ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ tóbi síta nípa òye rẹ̀.
13. Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omilọ́run a sì pariwo, ó mú kí ìkuùkù rusókè láti òpin ayé: ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.
14. Gbogbo ènìyàn jẹ́ aláìlóye àti aláìnímọ̀,ojú sì ti gbogbo alágbára pẹ̀lú ère rẹ̀,èrú ni ère rẹ̀, kò sì sí ẹ̀mí nínú wọn.