1. Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ fún yín ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì.
2. Èyí ni ohun tí Olúwa wí:“Má se tọ ọ̀nà àwọn orílẹ̀ èdètàbí kí ẹ jẹ́ kí àmù òfuurufú dààmúyín, nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀ èdè.
3. Nítorí pé asán ni asà àwọn ènìyàn,wọ́n gé igi láti inú igbó, oníṣẹ́-ọnàsì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀.