Jeremáyà 1:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. “Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pa lásẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọn dẹ́rù bà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn.

18. Ní òní èmi ti sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè alágbára, òpó ìrin àti odi idẹ sí àwọn Ọba Júdà, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.

19. Wọn yóò dojú ìjà kọọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́,” ni Olúwa wí.

Jeremáyà 1