Jẹ́nẹ́sísì 9:23-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ṣùgbọ́n Ṣémù àti Jáfétì mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòòhò baba wọn. Wọ́n kọjú ṣẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòòhò baba wọn.

24. Nígbà tí ọtí dá kúrò ní ojú Nóà, tí ó sì mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ àti ohun tí Ámù ọmọ rẹ̀ ṣe sí i.

25. Ó wí pé:“Ègún ni fún Kénánì.Ìránṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ni yóò máaṣe fún àwọn arákùnrin rẹ̀.”

26. Ó sì tún wí pé;“Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run ṢémùKénánì yóò máa ṣe ẹrú fún Ṣémù.

27. Ọlọ́run yóò mú Jáfétì gbilẹ̀,Jáfétì yóò máa gbé ní àgọ́ ṢémùKénánì yóò sì jẹ́ ẹrú fún-un.”

28. Nóà wà láàyè fún irínwó-ọdún-ó-dín-àádọ́ta (350) lẹ́yìn ìkún omi.

29. Àpapọ̀ ọjọ́ ayé Nóà jẹ́ ẹgbẹ̀rún-dín-ní-àádọ́ta ọdún, (950) ó sì kú.

Jẹ́nẹ́sísì 9