Jẹ́nẹ́sísì 8:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Omi sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbẹ kúrò lórí ilẹ̀, lẹ́yín àádọ́jọ ọjọ́, ó sì ti ń fà.

4. Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì ni ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ ṣórí òkè Árárátì.

5. Omi náà sì ń gbẹ si títí di oṣù kẹwàá. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹ́wàá, orí àwọn òkè sì farahàn.

6. Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Nóà sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀.

7. Ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde, tí ó ń fò káàkiri síwá àti ṣẹ́yìn títí omi fi gbẹ kúrò ní orí ilẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 8