Jẹ́nẹ́sísì 7:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Nóà sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Nóà.

10. Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé.

11. Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kéjì, tí Nóà pé ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún, ni gbogbo ìṣun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì sí sílẹ̀.

12. Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.

Jẹ́nẹ́sísì 7