5. Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lára àwọn tó lọ Éjíbítì lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kénánì pẹ̀lú.
6. Nisinsin yìí, Jósẹ́fù ni alábojútó fún gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, òun sì ni ó ń bojú tó ọkà títà fún gbogbo ènìyàn ìlú náà. Nítorí náà nígbà tí àwọn arákùnrin Jóṣẹ́fù dé, wọ́n tẹríba, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Jósẹ́fù.
7. Gbàrà tí Jósẹ́fù ti rí àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó ti dá wọn mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe bí i wí pé kò mọ̀ wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ líle sí wọn. Ó béèrè pé, “Níbo ni ẹ ti wá?”Wọ́n sì dáhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kénánì ni a ti wá ra oúnjẹ.”
8. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Jósẹ́fù mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, ṣíbẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kò mọ̀ ọ́n.
9. Nígbà náà ni ó rántí àlá rẹ̀ tí ó lá sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ayọ́lẹ̀wò (Amí) ni yín, ẹ wá láti wo àsírí ilẹ̀ wa ni”
10. Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ olúwa wa, àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá láti ra oúnjẹ ni,
11. Ọmọ baba ni wá, olóòótọ́ ènìyàn sì ni wá pẹ̀lú, àwa kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.”
12. Ó wí fún wọn pé, “Rárá! Ẹ wá láti wo àsírí ilẹ̀ wa ni”
13. Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kénánì. Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú.”
14. Jósẹ́fù wí fún wọn pé, “Bí mo ti wí fún un yín náà ni: Ayọ́lẹ̀wò ni yín!