Jẹ́nẹ́sísì 42:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Jákọ́bù mọ̀ pé ọkà wà ní Éjíbítì, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, “Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán?”

2. “Mo tí gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Éjíbítì. Ẹ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibẹ̀ kí ẹ sì rà wá fún wa, kí a má ba à kú.”

3. Nigbà náà ni mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin Jósẹ́fù sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì láti ra ọkà.

4. Ṣùgbọ́n Jákọ́bù kò rán Bẹ́ńjámínì àbúrò Jósẹ́fù lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bàá kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ síi.

5. Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lára àwọn tó lọ Éjíbítì lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kénánì pẹ̀lú.

6. Nisinsin yìí, Jósẹ́fù ni alábojútó fún gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, òun sì ni ó ń bojú tó ọkà títà fún gbogbo ènìyàn ìlú náà. Nítorí náà nígbà tí àwọn arákùnrin Jóṣẹ́fù dé, wọ́n tẹríba, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Jósẹ́fù.

Jẹ́nẹ́sísì 42