24. Àwọn siiri ọkà méje tí kò yó mọ sì gbé àwọn méje tí ó dára wọ̀nyí mì. Mo ṣọ àlá yìí fún àwọn onídán àn mi, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó le è túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”
25. Nígbà náà ni Jósẹ́fù wí fún Fáráò, “Ìtúmọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní. Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Fáráò.
26. Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, ṣiiri ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje: ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni.
27. Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni siiri ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrun ti rẹ̀ dànù tan: Wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú.
28. “Bí mo ti wí fún Fáráò ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Fáráò.