Jẹ́nẹ́sísì 4:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Káínì sì kúrò níwájú Ọlọ́run, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nódì ní ìhà ìlà oòrùn Édẹ́nì.

17. Káínì sì bá aya rẹ̀ lò pọ̀, ó sì lóyún, ó sì bí Énókù. Káínì sì tẹ ìlú kan dó, ó sì fi orúkọ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Énókù sọ ìlú náà.

18. Énókù sì bí Írádì, Írádì sì ni baba Méhújáélì, Méhújáélì sì bí Métúsáélì, Métúsáélì sì ni baba Lámékì.

19. Lámékì sì fẹ́ aya méjì, orúkọ èkíní ni Ádà, àti orúkọ èkejì ni Ṣílà.

Jẹ́nẹ́sísì 4