Jẹ́nẹ́sísì 39:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Nígbà tí Pọ́tífà gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi.

20. Ó sì ju Jósẹ́fù sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí.Ṣùgbọ́n, nígbà tí Jóṣẹ́fù wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀,

21. Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì sàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n (wọ́dà).

22. Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Jọ́ṣẹfù ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń se níbẹ̀.

23. Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Jósẹ́fù, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ lé.

Jẹ́nẹ́sísì 39