Jẹ́nẹ́sísì 39:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí wọ́n mú Jósẹ́fù dé Éjíbítì, Pótífà, ará Éjíbítì tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Fáráò. Òun ni olórí àwọn ọmọ ogun Fáráò. Ó ra Jósẹ́fù lọ́wọ́ àwọn ará Íṣímáẹ́lì tí wọ́n mú-un lọ ṣíbẹ̀.

2. Olúwa sì wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì bùkún-un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Éjíbítì.

3. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé.

4. Jósẹ́fù sì rí ojúrere Pọ́tífà, ó sì di asojú rẹ̀, Pọ́tífà fi Jósẹ́fù ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní.

Jẹ́nẹ́sísì 39