13. Ísírẹ́lì sì wí fún Jósẹ́fù pé, “Ṣé o mọ̀ pé, àwọn arákunrin rẹ ń da ẹran ní Ṣékémù, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.”Jósẹ́fù sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
14. O sì wí fún un pé, “Lọ wò bí àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn agbo ẹran bá wà ní àlàáfíà, kí o sì wá jíṣẹ́ fún mi.” Ó sì rán Jósẹ́fù lọ láti àfonífojì Ébúrónì.Nígbà tí Jósẹ́fù dé Ṣékémù,
15. Ọkùnrin kan sì rí i tí ó ń rìn kiri inú pápá, ó sì bi í pé, “Kín ni ò ń wá?”
16. Ó sì dáhùn pé, “Àwọn arákùnrin mi ni mò ń wá, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú agbo ẹran?”
17. Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Wọ́n ti kúrò ní ìhín, mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dótanì.’ ”Jósẹ́fù sì wá àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní tòsí Dótanì.
18. Ṣùgbọ́n bí wọ́n sì ti rí i tí ń bọ̀ lókèèrè, kí ó sì tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.
19. “Alálàá ni ń bọ̀ yìí,” ni wọ́n ń wí fún ara wọn.
20. “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á. Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ.”
21. Nígbà tí Rúbẹ́nì gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀,
22. Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn an, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láàyè nínú asálẹ̀ níbí.” Rúbẹ́nì sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀.
23. Nítorí náà, nígbà tí Jósẹ́fù dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀—