Jẹ́nẹ́sísì 37:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jákọ́bù sì gbé ilẹ̀ Kénánì ní ibi ti baba rẹ̀ ti gbé.

2. Èyí ni àwọn ìtàn Jákọ́bù.Nígbà tí Jósẹ́fù di ọmọ ọdún mẹ́tadínlógún (17), ó ń sọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwon ọmọ Bílíhà àti Sílípà aya baba rẹ̀ Jósẹ́fù sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn.

3. Jákọ́bù sì fẹ́ràn Jósẹ́fù ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tó kù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i. O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un.

4. Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kóríra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrin wọn.

5. Jósẹ́fù lá àlá kan, nígbà tí ó sì sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n túbọ̀ kórira rẹ̀ sí i.

6. O wí fún wọn pé “Ẹ fetí sí àlá tí mo lá:

7. Sáà wò ó, àwa ń yí ìdì ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìdì ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìdì ọkà tiyín sì dòòyì yí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un.”

Jẹ́nẹ́sísì 37