1. Wọ̀nyí ni ìran Ísọ̀, ẹni tí a ń pè ní Édómù.
2. Nínú àwọn ọmọbìnrin Kénánì ni Ísọ̀ ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Ádà ọmọbìnrin Élónì ará Hítì àti Óhólíbámà, ọmọbìnrin Ánà, ọmọ ọmọ Ṣíbéónì ará Hífítì.
3. Ó sì tún fẹ́ Báṣémátì ọmọ Ísímáélì arábìnrin Nébájótù.
4. Ádà bí Élífásì fún Ísọ̀, Báṣémátì sì bí Réúẹ́lì,