Jẹ́nẹ́sísì 34:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kan, Dínà ọmọbìnrin tí Líà bí fún Jákọ́bù jáde lọ bẹ àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà wò.

2. Nígbà tí Ṣékémù ọmọ ọba Hámórì ará Hífì rí i, ó mú un, ó sì fi ipá bá a lo pọ̀

3. Ọkàn rẹ sì fà sí Dínà ọmọ Jákọ́bù gan-an, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ó sì bá ọmọbìnrin náà sọ̀rọ̀-ìfẹ́.

4. Ṣékémù sì wí fún Hámórì bàbá rẹ̀ pé, “Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi bí aya.”

5. Nígbà tí Jákọ́bù gbọ́ ohun tí ó sẹlẹ̀ pé a fi ipá bá Dínà ọmọbìnrin òun lò pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ wà nínú pápá níbi tí wọ́n ti ń daran nítorí náà ó mú sùúrù títí tí wọ́n fi dé.

6. Ámórì baba Ṣékémù sì jáde wá láti bá Jákọ́bù sọ̀rọ̀.

7. Àwọn ọmọ Jákọ́bù sì ti oko dé, wọ́n sì gbọ́ ohun tí ó ṣelẹ̀ inú wọn sì bàjẹ́, ó sì ń bí wọn nínú gidigidi, nítorí pé, ohun àbùkù ńlá ni ó jẹ́ pé Ṣékémù bá ọmọ Jákọ́bù lò pọ̀-irú ohun tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá.

8. Hámórì sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkàn ọmọ mi Ṣékémù fà sí ọmọ rẹ. Jọ̀wọ́ fi fún un gẹ́gẹ́ bí aya.

9. Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbéyàwó láàrin ara wa, kí àwọn ọmọ yín kó máa fẹ́ àwọn ọmọ wa.

Jẹ́nẹ́sísì 34