Jẹ́nẹ́sísì 33:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Èmi bẹ̀ ọ́, máa lọ ṣíwájú ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ó sì máa rọra bọ̀, títí èmi àti àwọn ọmọ yóò fi dé ọdọ̀ olúwa mi ní Ṣéírì.”

15. Ísọ̀ wí pé, “Jẹ́ kí n fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ nínú àwọn ọkùnrin mi nígbà náà.”Jákọ́bù wí pé, “Èéṣe, àní kí n sáà rí ojú rere olúwa mi?”

16. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Ísọ̀ padà lọ sí Ṣéírì.

17. Jákọ́bù sì lọ sí Ṣúkótù, ó sì kọ́ ilé fún ara rẹ̀, ó sì ṣe ọgbà fún àwọn ẹran. Ìdí èyí ní a fi ń pe ibẹ̀ ní Ṣúkótù.

18. Lẹ́yìn ìgbà tí Jákọ́bù tí Padani-Árámù dé: Àlàáfíà ni Jákọ́bù dé ìlú Sẹ́kẹ́mù ní ilẹ̀ Kénánì, ó sì pàgọ́ sí ìtòòsí ìlú náà.

19. Ó sì ra ilẹ̀ kan tí ó pàgọ́ sí ni ọgọ́rùn-ún owó fàdákà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì tíí ṣe bàbá Sẹ́kẹ́mù.

20. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan tí ó pè ní El Elohe Ísírẹ́lì (Ọlọ́run Ísírẹ́lì).

Jẹ́nẹ́sísì 33