Jẹ́nẹ́sísì 31:53-55 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

53. Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Náhórì, àti Ọlọ́run baba wọn ṣe ìdájọ́ láàrin wa.”Báyìí ni Jákọ́bù dá májẹ̀mu ní orúkọ Ọlọ́run Ẹ̀rù-Ísáákì baba rẹ̀.

54. Jákọ́bù sì rúbọ níbẹ̀ ni orí òkè, ó sì pe àwọn ẹbí rẹ̀ láti jẹun. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹun, ibẹ̀ náà ni wọ́n sùn ní ọjọ́ náà.

55. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Lábánì fi ẹnu ko àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì súre fún wọn. Lábánì sì padà lọ sí ilé.

Jẹ́nẹ́sísì 31