Jẹ́nẹ́sísì 31:17-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nígbà náà ni Jákọ́bù gbé àwọn ọmọ àti aya rẹ̀ gun ràkunmí

18. Ó sì da gbogbo agbo ẹran rẹ̀ ṣáájú pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tí ó ti kó jọ ni Padani-Árámù, láti lọ sí ọ̀dọ̀ Ísáákì baba rẹ̀ ni ilẹ̀ Kénánì.

19. Nígbà tí Lábánì sì lọ láti rẹ́run àgùntàn, Rákélì sì jí àwọn ère òrìṣà ilé baba rẹ̀.

20. Síwájú sí i, Jákọ́bù tan Lábánì ará Árámù, nítorí kò sọ fún un wí pé òun ń sá lọ.

21. Ó sì sá lọ pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ni, ó sì la odò kọjá (Yúfúrátè), ó sì kọrí sí àwọn ilẹ̀ olókè ti Gílíádì.

Jẹ́nẹ́sísì 31