12. Ó sì wí pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wò ó, gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran jẹ́ oni tótòtó, onílà àti alámì, nítorí mo ti rí gbogbo ohun ti Lábánì ń ṣe sí ọ.
13. Èmi ni Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì, níbi tí ìwọ ti ta òróró sí òpó (ọ̀wọ́n), ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti sìn mi. Nísinsin yìí, kúrò ní ilẹ̀ yìí kíákíá kí o sì padà sí ilẹ̀ ibi tí a gbé ti bí ọ.’ ”
14. Nígbà náà ni Rákélì àti Líà dàhún pé, “Ìpín wo ní nínú ogún baba wa?
15. Àjèjì ha kọ́ ni ó kà wá sí? Kì í ṣe pé torí pé ó tà wá nìkan, ṣùgbọ́n ó ti ná gbogbo owó tí ó gbà lórí wa tán.
16. Dájúdájú gbogbo ọrọ̀ ti Ọlọ́run gbà lọ́wọ́ baba wa fún ọ, tiwa àti ti àwọn ọmọ wa ní í ṣe. Nítorí náà ohun gbogbo tí Ọlọ́run bá páṣẹ fun ọ láti ṣe ni kí ìwọ kí ó ṣe.”
17. Nígbà náà ni Jákọ́bù gbé àwọn ọmọ àti aya rẹ̀ gun ràkunmí
18. Ó sì da gbogbo agbo ẹran rẹ̀ ṣáájú pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ tí ó ti kó jọ ni Padani-Árámù, láti lọ sí ọ̀dọ̀ Ísáákì baba rẹ̀ ni ilẹ̀ Kénánì.
19. Nígbà tí Lábánì sì lọ láti rẹ́run àgùntàn, Rákélì sì jí àwọn ère òrìṣà ilé baba rẹ̀.