Jẹ́nẹ́sísì 30:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Rákélì sì wí pé, “Ọlọ́run ti ṣe ìdájọ́ mi; ó sì ti gbọ́ ohún ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ni ọmọkùnrin kan.” Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Dánì.

7. Bílíhà, ọmọ ọ̀dọ̀ Rákélì sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kéjì fún Jákọ́bù.

8. Nígbà náà ni Rákélì wí pé, “Mo ti bá ẹ̀gbọ́n mi ja ìjàkadì ńlá, èmi sì ti borí.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Náfítalì.

9. Nígbà tí Líà sì ri pé òun ko tún lóyún mọ́, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, Ṣílípà fún Jákọ́bù bí aya.

Jẹ́nẹ́sísì 30