17. Ọlọ́run sì gbọ́ tí Líà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kárùn-un fún Jákọ́bù.
18. Nígbà náà ni Líà wí pé, “Ọlọ́run ti ṣẹ̀san ọmọ ọ̀dọ̀ mi ti mo fi fún ọkọ mi fún mi,” ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísákárì.
19. Líà sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jákọ́bù.
20. Nígbà náà ni Líà tún wí pé “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn iyebíye, nígbà yìí ni ọkọ mi yóò máa bu ọlá fún mi.” Nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ni Ṣébúlúnì.
21. Lẹ́yìn èyí, ó sì bí ọmọbìnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dínà.
22. Nígbà náà ni Ọlọ́run rántí Rákélì, Ọlọ́run sì gbọ́ tirẹ̀, ó sì sí i ní inú.
23. Ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan ó sì wí pé, “Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn mi kúrò.”
24. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ni Jóṣẹ́fù, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ kí Olúwa kí ó fi ọmọkùnrin mìíràn kún-un fún mi.”
25. Lẹ́yìn tí Rákélì ti bí Jóṣẹ́fù, Jákọ́bù wí fún Lábánì pé, “Jẹ́ kí èmi máa lọ sí ilẹ̀ mi tí mo ti wá.
26. Kó àwọn ọmọ àti ìyàwó mi fún mi, àwọn ẹni tí mo ti torí wọn sìn ọ́. Ki èmi lè máa bá ọ̀na mi lọ. O sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ tó”
27. Ṣùgbọ́n Lábánì wí fún un pé, “Bí o bá ṣe pé mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ dúró, nítorí, mo ti ṣe àyẹ̀wò rẹ, mo sì rí i pé Olúwa bùkún mi nítorí rẹ.
28. Sọ ohun tí o fẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ, èmi yóò sì san án.”