Jẹ́nẹ́sísì 30:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Rákélì rí i pe òun kò bímọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara sí Líà, arabìnrin rẹ̀, ó sì wí fún Jákọ́bù pé, “Fún mi lọmọ, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó kú”

2. Inú sì bí Jákọ́bù sí i, ó sì wí pé, “Èmi ha wà ní ipò Olúwa, ẹni tí ó mú ọ yàgàn bí?”

3. Nígbà náà ni Rákélì wí pé, “Bílíhà ìránṣẹ́bìnrin mi nìyìí, bá a lòpọ̀, kí ó ba à le bí ọmọ fún mi, kí èmi si le è tipaṣẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.”

Jẹ́nẹ́sísì 30