11. Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èṣo igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?”
12. Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èṣo igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”
13. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?”Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.”
14. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí,“Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìnàti gbogbo ẹran igbó tó kù lọ!Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́,ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.