Jẹ́nẹ́sísì 28:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. àti pé, Jákọ́bù ti gbọ́ràn sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Árámù.

8. Nígbà náà ni Ísọ̀ mọ bí Ísáákì baba rẹ ti kórìíra àwọn ọmọbìnrin Kénánì tó.

9. Nítorí náà ó tọ Íṣímáélì lọ, ó sì fẹ́ Máhálátì, arábìnrin Nébájótù, ọmọbìnrin Ísímáélì tí í ṣe ọmọ Ábúráhámù. Ó fẹ́ ẹ, kún àwọn ìyàwó tí ó ti ní tẹ́lẹ̀

10. Jákọ́bù kúrò ní Bíáṣébà, ó sì kọrí sí ìlú Áránì.

11. Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń sú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn.

Jẹ́nẹ́sísì 28