Jẹ́nẹ́sísì 28:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń sú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn.

12. Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀.

13. Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run Baba rẹ Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísáákì, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún.

Jẹ́nẹ́sísì 28