43. Nítorí náà ọmọ mi, ṣe ohun tí èmi yóò sọ fún ọ: Ṣá lọ sọ́dọ̀ Lábánì ẹ̀gbọ́n mi ní Háránì.
44. Dúró sí ibẹ̀ títí di ìgbà tí inú Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ yóò fi rọ̀.
45. Nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ kò bá bínú sí ọ mọ́, tí ó sì ti gbàgbé ohun tí ìwọ ṣe sí i, èmí ó ránṣẹ́ sí ọ láti padà wá, Èéṣe tí èmi ó fi pàdánù ẹ̀yin méjèèjì ní ọjọ́ kan náà?”
46. Nígbà náà ni Rèbékà wí fún Isaaki pé, “Ayé sì sú mi nítorí àwọn ọmọbìnrin Hétì wọ̀nyí. Bí Jákọ́bù bá fẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Hétì wọ̀nyí, ó kúkú sàn kí n má wà láàyè.”