Jẹ́nẹ́sísì 27:33-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Nígbà náà ni Ísáákì wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé? Mo sì ti súre fún un sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un”

34. Nígbà tí Ísọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ baba rẹ̀, ó ké, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún kíkorò, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Baba mi súre fún èmi náà, àní fún èmi náà pẹ̀lú.”

35. Ṣùgbọ́n Ísáákì wí pé, “Àbúrò rẹ ti fi ẹ̀tàn wá, ó sì ti gba ìbùkún rẹ lọ”

36. Ísọ̀ sì wí pé, “Lásán ni a pe orúkọ rẹ̀ ní Jákọ́bù, (Arẹ́nijẹ) bí? Ní ìgbà méjì yìí ni ó ti tàn mí jẹ: ní àkọ́kọ́, ó gba ogún ìbí mi, nísinsinyìí, ó tún gba ìbùkún mi! Áà! Baba mi, ṣe o kò wá fi ìre kankan sílẹ̀ fun mi ni?”

37. Ísáákì sì dá Ísọ̀ lóhùn pé, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ àti àwọn ìbátan rẹ ni mo fi ṣe ìránṣẹ́ fún-un, àti oúnjẹ àti wáìnì ni mo ti fi lé e lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, kí ni ó tún kù tí ǹ bá tún fún ọ báyìí ọmọ mi?”

38. Ísọ̀ sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Ṣe ìre kan ṣoṣo ni ìwọ ní lẹ́nu ni baba mi?, Ṣúre fún èmi náà, baba mi.” Ísọ̀ sì sunkún kíkankíkan.

39. Ísáákì bàbá rẹ̀ sì dá a lóhùn pé,“Ibùjòkòó rẹyóò jìnnà sí ọ̀rá ilẹ̀,àti sí ìrì ọ̀run láti òkè wá.

Jẹ́nẹ́sísì 27