Jẹ́nẹ́sísì 24:24-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ó dáhùn pé, “Bétúélì ọmọ tí Mílíkà bí fún Náhórì ni baba mi”

25. Ó sì fi kún un pé, “A ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ koríko àti oúnjẹ fún àwọn ràkunmí yín àti yàrá pẹ̀lú fún-un yín láti wọ̀ sí.”

26. Nígbà náà ni ọkùnrin náà tẹríba, ó sì sin Olúwa.

Jẹ́nẹ́sísì 24