Jẹ́nẹ́sísì 22:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. dájúdájú, Èmi yóò bùkún ọ, Èmi yóò sì mú kí ìran rẹ yìí kí ó pọ̀ bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí i yanrìn etí òkun. Irú ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀ta wọn,

18. àti nípaṣẹ̀ irú ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀ èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́ràn sí mi lẹ̀nu”

19. Nígbà náà ni Ábúráhámù padà tọ àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn sì padà lọ sí Báá-Ṣébà Ábúráhámù sì dúró ní Báá-Ṣébà.

Jẹ́nẹ́sísì 22