Jẹ́nẹ́sísì 21:26-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ṣùgbọ́n Ábímélékì dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe èyí, ìwọ kò sì sọ fún mi tẹ́lẹ̀, òní ni mo sẹ̀sẹ̀ ń gbọ́ báyìí.”

27. Ábúráhámù sì mú àgùntàn àti màlúù wá, ó sì kó wọn fún Ábímélékì. Àwọn méjèèjì sì dá májẹ̀mú.

28. Ábúráhámù sì ya abo ọ̀dọ́-àgùtàn méje nínú agbo àgùntàn rẹ̀ sọ́tọ̀.

29. Ábímélékì sì béèrè lọ́wọ́ Ábúráhámù pé, “Kín ni ìtumọ̀ yíyà tí ìwọ ya àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn méje wọ̀nyí sọ́tọ̀ sí.”

30. Ó da lóhùn pé “Gba àwọn abo ọ̀dọ́-àgùtàn méje wọ̀nyí lọ́wọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.”

Jẹ́nẹ́sísì 21