Jẹ́nẹ́sísì 21:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sì fi oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ hàn sí Ṣárà, sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ti sèlérí fún-un.

2. Ṣárà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Ábúráhámù ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní àkókò náà gan-an tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un.

3. Ábúráhámù sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sárà bí fun un ní Ísáákì.

4. Nígbà tí Ísáákì pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, Ábúráhámù sì kọ ọ́ ní ilà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún-un.

5. Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Ábúráhámù nígbà tí ó bí Ísáákì.

6. Ṣárà sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.”

Jẹ́nẹ́sísì 21