10. Ábímélékì sì bi Ábúráhámù pé, “Kín ló dé tí ìwọ fi ṣe èyí?”
11. Ábúráhámù sì dáhùn pé, “Mo ṣe èyí nítorí mo rò nínú ara mi pé, ẹ̀yin tí ẹ wà níhìn-ín, ẹ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, pé, ẹ sì le pa mí nítorí aya mi.
12. Yàtọ̀ fún ìyẹn, òtítọ́ ni pé arábìnrin mi ni. Ọmọ baba kan ni wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a kì í ṣe ọmọ ìyá kan. Mo sì fẹ́ ẹ ní aya.
13. Nígbà tí Ọlọ́run sì mú mi rìn kiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Èyí ni ọ̀nà tí ó lè gbà fi hàn pé ó fẹ́ràn mi: Gbogbo ibi tí a bá dé máa sọ pé, “Arákùnrin rẹ ni mí.” ’ ”
14. Nígbà náà ni Ábímélékì mú àgùntàn àti màlúù wá, àti ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ó sì kó wọn fún Ábúráhámù, ó sì dá Sárà aya rẹ̀ padà fún un.