Jẹ́nẹ́sísì 2:5-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí Olúwa Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀.

6. Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀.

7. Olúwa Ọlọ́run sì mọ ènìyàn láti ara erùpẹ̀ ilẹ̀, ó si mí èémí sí ihò imú rẹ̀, èémí ìyè, ènìyàn sì di ẹ̀dá alààyè.

8. Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Édẹ́nì ní ìhà ìlà oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí.

9. Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀: àwọn igi tí ó dùn-ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárin ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà.

10. Odò kan sì ń ti Édẹ́nì sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin.

11. Orúkọ èkínní ni Písónì: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Háfílà ká, níbi tí wúrà gbé wà.

12. (Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjíá àti òkúta oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú).

13. Orúkọ odò kejì ni Gíhónì: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kúsì ká.

14. Orúkọ odò kẹta ni Tígírísì: òun ni ó sàn ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Áṣúrì. Odò kẹ́rin ni Yúfúrátè.

Jẹ́nẹ́sísì 2