Jẹ́nẹ́sísì 18:20-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Olúwa sì wí pé, igbe Ṣódómù àti Gòmórà pọ̀ púpọ̀ àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jọjọ.

21. “Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ síbẹ̀ láti ṣe ìwádìí igbe tí ó dé sí etí ìgbọ́ mi nípa wọn, kí èmi sì mọ òtítọ́ tí ó wà níbẹ̀.”

22. Àwọn ọkùnrin náà yí padà, wọ́n sì ń lọ sí ìhà Ṣódómù. Ṣùgbọ́n Ábúráhámù dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa.

23. Nígbà náà ni Ábúráhámù súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa ènìyàn rere àti ènìyàn búrurú run papọ̀ bí?”

24. “Bí ó bá ṣe pé Ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, Ìwọ yóò ha run-ún, Ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà?

25. Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tó bi?”

26. Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta (150) olódodo ní ìlú Ṣódómù, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tí wọn.”

27. Ábúráhámù sì tún tẹ̀ṣíwájú pé, “Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú sí Olúwa, èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú,

28. bí ó bá ṣe pe olódodo márùn-dín-làádọ́ta (45) ni ó wà nínú ìlú, Ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?” Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùn-dín-láàádọ́ta nínú rẹ̀.”

Jẹ́nẹ́sísì 18