Jẹ́nẹ́sísì 18:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sì farahan Ábúráhámù ní tòsí àwọn igi ńlá Mámúrè, bí ó ti jókòó ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, nígbà tí ọjọ́ kanrí tí oòrùn sì mú.

2. Ábúráhámù gbójú sókè, ó sì rí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọn dúró nítòsí rẹ̀. Nígbà tí ó rí wọn, ó sáré láti lọ pàdé wọn, ó sì tẹríba bí ó ti ń kí wọn.

3. Ó wí pé, “Bí mo bá rí ojú rere yín Olúwa mi, ẹ má ṣe lọ láì yà sọ́dọ̀ ìránṣẹ́ yín.

Jẹ́nẹ́sísì 18