Jẹ́nẹ́sísì 17:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Gbogbo ọmọkùnrin tí kò bá kọ ilà, tí a ko kọ ní ilà abẹ́, ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó da májẹ̀mú mi”

15. Ọlọ́run wí fún Ábúráhámù pé, “Ní ti Ṣáráì, aya rẹ̀, ìwọ kì yóò pè é ní Ṣáráì bí kò ṣe Ṣárà.

16. Èmi yóò bùkún fún-un, Èmi yóò sì fun ọ ní ọmọkùnrin kan nípaṣẹ̀ rẹ̀. Èmi yóò bùkún-un, yóò sì di ìyá àwọn orílẹ̀ èdè, àwọn ọba àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì ti ara rẹ̀ jáde wá.”

Jẹ́nẹ́sísì 17