7. Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni Olúwa tí ó mú ọ jáde láti Úrì ti Kálídéà láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.”
8. Ṣùgbọ́n Ábúrámù wí pé, “Olúwa Ọlọ́run, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?”
9. Nítorí náà, Olúwa wí fún-un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́tamẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”
10. Ábúrámù sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjìméjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣugbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn.