Jẹ́nẹ́sísì 14:22-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ṣùgbọ́n Ábúrámù dá ọba Ṣódómù lóhùn pé, “Mo ti búra fún Olúwa, Ọlọ́run ọ̀gá ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè,

23. pé, èmi kì yóò mú ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ se tèmi, ìbáà kéré bí orí abẹ́rẹ́, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Ábúrámù di ọlọ́rọ̀.’

24. Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Ánérì, Ésíkólì àti Mámúrè. Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn.”

Jẹ́nẹ́sísì 14