11. Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Ṣódómù àti Gòmórà àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ.
12. Wọ́n sì mú Lọ́tì ọmọ arákùnrin Ábúrámù tí ń gbé ní Ṣódómù àti gbogbo ohun-ìní rẹ̀.
13. Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Ábúrámù, ará Ébérù. Ábúrámù sá ti tẹ̀dó sí igbó igi Óákù tí ó jẹ́ ti Mámúrè ará Ámórì, arákùnrin Ésíkólì àti Ánérì: àwọn ẹni tí ó ń bá Ábúrámù ní àṣepọ̀.
14. Nígbà tí Ábúrámù gbọ́ wí pé, a di Lọ́tì ní ìgbékùn, o kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ́ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó-lé-lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì ènìyàn (318), ó sì lépa wọn títí dé Dánì.
15. Ní ọ̀gànjọ́ òru, Ábúrámù pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí méjì, ó sì kọlù wọ́n, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn títí dé Oba, ní àríwá Dámásíkù.
16. Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọ́tì pẹ̀lú ohun-ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tó kù.
17. Nígbà tí Ábúrámù ti ṣẹ́gun Kedolaómérì àti àwọn ọba tí ó pẹ̀lú rẹ̀, ọba Ṣódómù lọ pàdé e rẹ̀ ní àfonífojì Ṣáfè (èyí tí ó túmọ̀ sí Àfonífojì ọba).