12. Ábúrámù ń gbé ni ilẹ̀ Kénánì, Lọ́tì sì jókòó ní ìlú agbègbè àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Ṣódómù.
13. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ṣódómù jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́sẹ̀ gidigidi ni ìwájú Olúwa.
14. Olúwa sì wí fún Ábúrámù lẹ́yìn ìpínyà òun àti Lọ́tí pé, “Gbé ojú rẹ sókè níṣinṣin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúsù, sí ìlà oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀.
15. Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ní èmi ó fi fún ọ àti irú ọmọ rẹ láéláé.