Jẹ́nẹ́sísì 10:11-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí dé Áṣíríà, níbi tí ó ti tẹ ìlú Nínéfè, Réhóbótì àti Kálà,

12. àti Résínì, tí ó wà ní àárin Nínéfè àti Kálà, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí.

13. Mísíráímù ni baba ńlá àwọn aráLúdì, Ánámì, Léhábì, Náfítúhímù.

14. Pátírúsímù, Kásílúhímù (èyí tí í ṣe baba ńlá àwọn Fílístínì) àti Káfítórímù.

15. Kénánì ni baba àwọn aráSídónì (èyi ni àkọ́bí rẹ̀), àti àwọn ara Hítì.

16. Àwọn ará Jébúsì, Ámórì, Gágásì.

17. Hífì, Áríkì, Sínì,

18. Áfádì, Ṣémárì àti Hámátì.Nígbà tí ó ṣe, àwọn ẹ̀yà Kénánì tàn kálẹ̀.

19. Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kénánì sì dé Ṣídónì, lọ sí Gérárì títí dé Gásà, lọ sí Sódómù, Gòmórà, Ádímà àti Ṣébóìmù, títí dé Láṣà.

20. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ámù, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.

21. A bí àwọn ọmọ fún Ṣémù tí Jáfétì jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣémù sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Ébérì.

22. Àwọn ọmọ Ṣémù ni:Élámù, Ásọ̀, Áfákísádì, Lúdì àti Árámù.

23. Àwọn ọmọ Árámù ni:Úsì, Úlì, Gétérì àti Méṣékì.

24. Áfákísádì ni baba Ṣélà,Ṣélà yìí sì ni ó bí Ébérì.

25. Ébérì sì bí ọmọ méjì:ọ̀kan sì ń jẹ́ Pélégì, nítorí ní ìgbà ayé rẹ̀ ni ilẹ̀ ayé pín sí oríṣìíríṣìí ẹ̀yà àti èdè. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jókítanì.

26. Jókítanì sì bíÁlímádádì, Ṣéléfì, Hásámáfétì àti Jérà.

27. Hádórámù, Húsálì, Díbílà.

28. Óbálì, Ábímáélì, Ṣébà.

29. Ófírì, Áfílà àti Jóbábù. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jókítanì.

30. Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Méṣà títí dé Ṣéfárì, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà oòrùn.

31. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣémù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀ èdè wọn.

Jẹ́nẹ́sísì 10