8. Ọlọ́run sì pe òfúurufú ní “Ọ̀run,” àsálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì.
9. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojúkan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.
10. Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “Ilẹ̀” àti àpapọ̀ omi ní “Òkun:” Ọlórun sì rí i wí pé ó dára.
11. Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èṣo wá àti igi tí yóò máa so èṣo ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.