Jákọ́bù 1:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá bèèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyè méjì dàbí ìgbì omi òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè.

7. Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé, òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́wọ́ Olúwa;

8. Ó jẹ ènìyàn oníyèméjì aláìllèdúró ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo.

Jákọ́bù 1