Ísíkẹ́lì 9:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo gbọ́ tó kígbe pé, “Mú àwọn olùṣọ́ ìlú súnmọ́ ìtòsí, kí olúkúlùkù wọn mú ohun ìjà olóró lọ́wọ́.”

2. Lójú ẹsẹ̀ ni ọkùnrin mẹ́fà (6) jáde láti ẹnu ọ̀nà òkè tó kọjú sí ìhà àríwá, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà olóró lọ́wọ́ wọn. Ọkùnrin kan tó wọ aṣọ funfun lẹlẹ wa láàrin wọn, pẹ̀lú ohun ìkọ̀we lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo wọn sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ.

Ísíkẹ́lì 9