13. Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nígbà tí òkú àwọn ènìyàn wọn bá wà níbẹ̀ láàrin òrìṣà wọn yí pẹpẹ wọn ká, lórí àwọn òkè gíga gbogbo, àti lórí góńgó òkè àti lábẹ́ igi tútù àti lábẹ́ igi óákù-níbi tí wọ́n ti ń fi tùràrí dídùn rúbọ̀ sí gbogbo òrìṣà wọn.
14. Èmi yóò na ọwọ́ mi jáde sí wọn láti mú kí ilẹ̀ náà ṣòfò kí ó sì dahoro dé aṣálẹ̀ ìhà Díbílà-ní gbogbo ibùgbé wọn. Nígbà náà ni wọn ó mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”