3. Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ.
4. Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná. Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Ísírẹ́lì.
5. “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èyí ní Jérúsálẹ́mù, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká.
6. Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ̀ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀ èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, kò sì pa ìlànà mi mọ́.