Ísíkẹ́lì 5:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ìrun yìí níná láàrin ìlú. Mú ìdá kan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú. Kí o sì tú ìdá kan yóòkù ká sínú afẹ́fẹ́. Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká.

3. Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ.

4. Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná. Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Ísírẹ́lì.

5. “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Èyí ní Jérúsálẹ́mù, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká.

Ísíkẹ́lì 5