Ísíkẹ́lì 48:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn: Ní òpin àríwá, Dánì yóò ni ìpín kan; èyí yóò tẹ̀lé ọ̀nà Hétílónù sí létí Hámátì; Hásárì Énánù àti ààlà àríwá tí Dámásíkù tí ó kángun sí Hámátì yóò jẹ́ ara ààlà rẹ̀ láti ìhà ìlà oòrùn títí lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn.

2. “Àsárì yóò ní ìpín kan; yóò jẹ́ ààlà agbégbé dánì láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ oòrùn.

Ísíkẹ́lì 48